Ìjọba Nàìjíríà rán èèyàn sí Igboho lọ́gbà ẹ̀wọ̀n Benin láti jáwọ́ lórí Yoruba Nation kí wọ́n lè fi sílẹ̀ – Banji Akintoye

Aworan Oloye Banji Akintoye

Oríṣun àwòrán, Others

Adari Ilana Omo Oodua, Oloye Banji Akintoye ni bi Oloye Sunday Adeyemo ti ọpọ mọ si Sunday Igboho ṣe gba itusilẹ lorilẹede Benin Republic jẹ ohun aṣeyọri fun oun pupọ,lati ri i pe oun sin Igboho de ibi ti ẹru ko ti ni ba mọ.

Ninu ifọrọwerọ kan to ba BBC News Yoruba ṣe, Oloye Akintoye lori ipa to ko lori bi Igboho ṣe gba itusilẹ kuro ni orilẹede Benin Republic ati awọn nnkan to waye lasiko to wa ni ọgba ẹwọn nibẹ.

O ni ọpọ igba ni ijọba orilẹede Naijiria ran asoju ijọba wa si atimọle ti Sunday Igboho wa lorilẹede Benin Republic lati rọọ pe ko jawọ ninu ija fun idasilẹ Yoruba Nation to gunle sugbọn to ni Sunday Igboho kọ jalẹ.

“Mọ fẹ sọ itan kan fun yin, ọkan lara awọn to lagbara ju lorilẹede Naijiria, Ọgagun fẹyin ti ni, Ọga ologun lorilẹede Naijiria ni ẹni naa, asoju ijọba Naijiria lorilẹede Benin Republic ni, lo ba wa ba Sunday logba ẹwọn, o si wa ni ọgba ẹwọn lasiko naa, ki ṣe igba igbele.

“O wa ri Sunday, wọn lọ pe Sunday wa ninu ọgba ẹwọn pe ko wa pade ẹni naa ni ile kekere kan, o ni ijọba Naijiria lo ran oun pe ki oun wa ri Sunday Igboho, pe to ba gbe ọrọ Yoruba Nation ju sọnu, oun a buwọlu iwe to wa lọwọ oun yii, ..."

O ni wọn ti ks sinu lẹta ti aṣoju ijọba NAijiria naa mu wa lọjọ naa pe ko tọwọ bọ iwe naa pe oun ko ni da si ọrọ Yoruba Nation mọ yoo gba itusilẹ, wọn yoo si tun pese baluu ti yoo gbe de ilu Abuja pẹlu ayẹsi ati idanilọla.

“Sunday wa ni 'ki oun tọwọ bọwe, to tumọ si pe ki oun gbe Yoruba Nation silẹ, ki awọn ijọba le ma ṣe nnkan ti wọn fẹ. Sunday ni ko da ki oun kọ ẹyin si awọn eeyan Yoruba>

“Sunday ni oun ko ki ṣe ọmọ Yoruba ti wọn le fi owo tan, pe ki wọn wo ẹrẹkẹ ohun pẹlu ila, oun ko le kọ ẹyin si ilẹ Baba oun, ẹni to wa ko le duro mọ, to si ni lati lọ.”

Aworan Sunday Adeyemo

Oríṣun àwòrán, Instagram/SundayIgboho1

Ki lo sẹlẹ saaju

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ti a ko ba gbagbe Oloye Sunday Igboho lo di ero atimọle lorilẹede Benin Republic lẹyin ti awọn agbofinro mu lasiko to gbero lati gba orilẹede Benin lọ si orilẹede Germany lẹyin ti ikọ DSS ṣe ikọlu si ile rẹ niluu Ibadan lọrilẹede Naijiria.

Lati igba ti Igboho ti wa ni atimọle ni Oloye Banji Akintoye ti morile orilẹede Benin Republic to si ni oun ko ni kuro ayafi ti Igboho ba gba itusilẹ.

“Igbesẹ ti mo gbe pọ. ti n ba ni ki ma kọ, ma kọ odidi iwe kan tan sugbọn mo dupẹ lọwọ Ọlọrun pe eyi yọri si daada.

“Ariwo Sunday Igboho ni awọn ọmọ Yoruba n pa, wọn si ṣe ọpọlọpọ iranlọwọ fun wa. Awọn Yoruba ti wọn bi ni Benin Republic naa dide si wa, wọn tun kọ lẹta si Aarẹ pe ẹni ti ẹ ti mọle yii, ọmọ iya ati baba wa ni, ko le wa nibi bayii nitori ko ṣe si ofin.

“Ni ijẹta ti mo sin Sunday jade kuro lorilẹede yii, awọn eeyan ti mo kọkọ pe ni awọn ọmọ orilẹede Benin Republic pe nnkan ti a fẹ ti bọ si.

“Gbogbo awọn to lẹnu ninu ilu ti mo kan si, ti wọn si ṣe atilẹyin fun mi lori ọrọ Sunday Igboho. Igba ti ẹru n ba mi, wọn duro ti mi pe ki n ma foya.

"Loju mi, Sunday pẹ ju lọgba ẹwọn..."

Akintoye tẹsiwaju pe oun ko lero pe Igboho yoo lo to asiko to lo lọgba nitori oun iyalẹnu lo jẹ fun ọpọlọpọ.

O ni ọpọlọpọ ẹbẹ ni oun bẹ ki wọn fi Sunday Igboho silẹ pe ko kuro ni atimọle sugbọn ko gbọdọ kuro lorilẹede Benin.

“A bẹbẹbẹ ki wọn to fi Sunday Igboho silẹ ni ahamọ, wọn tun wa fi silẹ, wọm ni ko gbọdọ kuro lorilẹede wọn, ko tun wa ni igbele, ẹn iyẹn lawa, ti a ro pr oṣu kan toto fi di ọdun kan ọdun meji

Igboho o ṣe ẹnikẹni lorilẹede Naijiria, o le wale

Adari Ilana wa jẹ ko di mimọ pe Igboho ko sẹ ẹnikẹni tabi sẹ si ofin lorilẹede Naijiria, to si le pada wa lasiko to ba wu lati wa.

“Ko ni ẹsẹ kankan to ẹni kankan ni Naijiria, nnkan ti awọn alasẹ ko fẹ gbọ nipe ẹya kan fẹ kuro ni Naijiria“.

Akintoye tẹsiwaju pe Sunday Igboho ko fi igba kankan kuro tabi mu ẹnu kuro lori ọrọ Yoruba Nation lasiko to wa ni ọgba ẹwọn.

“Ko si ẹnikẹni to le fi ẹnu rẹ sọrọ pe Sunday sọ fun oun pe ko ṣe Yoruba Nation pe ọrọ naa ti su oun.

“Ibi to wa tẹlẹ, ọrọ rẹ ko le jagba sugbọn nibayii to ti jade, o le sọrọ sita.”

Ẹ sọ fun ijọba ki wọn tẹle asẹ ileẹjọ, ki wọn san owo mabinu fun Igboho- Adebanjo

Ọkan lara awọn agbagbagba ninu ẹgbẹ Afenifere, Oloye Ayo Adebanjo ni o ṣeeṣe ko fun ijọba lati tẹle asẹ ileẹjọ to palasẹ pe ki wọn san owo oe wọn ba ile Sunday Igboho lasiko ti wọn ṣe ikọlu si.

Adebanjo nio o ṣe ni laanu pe ijọba to wa lode yii ko fẹ alatako sugbọn inu oun dun si itusilẹ Sunday Igboho.

“Nnkan ti Ọlọrun ki a ṣe ni a ṣe, o ka da bi awọn ijọba ko fẹ alatako, wọn dẹ kọ lati tẹle ofin.

“Ijọba buruku ni a ni, ileẹjọ pasẹ, wọn kọ lati tele, wọn fẹ pa, wọn ko ri pa, o gbe wọn lọ si ileẹjọ lẹyin ti wọn ba dukia rẹ,

“Ki wọn lọ tẹle idajọ ti ileẹjọ fun wọn tabi ki wọn ri idajọ Ọlọrun.”

Adebanjo wa ni ohun ti le sọ biya Igboho le pada si orilẹede sugbọn ko si ma gbadun ni bi to wa lasiko yii.